Láti ọwọ́ Akeem Alao
Ẹ̀tọ́ aráàlú ni láti dìbò fún ẹni tí ọkàn wọn yàn láàyò. Ètò ìdìbò jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tí aráàlú ń gbà láti kópa nínú ètò ìṣèjọba ìlú.
Ìdìbò ni irinṣẹ́ tí aráàlú ń lò láti yan aṣojú fún àkóso ìlú, ìjọba ìbílẹ̀, tabi ìletò. Àléébù ńlá ni àìkópa nínú ètò ìdìbò yóò jẹ fún aráàlú. Èyí lèṣe ìdíwọ́ fún ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ìlú.
Èyí gan ni ìdí abájọ tí ó fi di dandan kí á tú yẹ́yẹ́ síta fún ìdìbò ọjọ́ Àbámẹ́ta Ọ̀sẹ̀ yíì.
Fún àwọn olùgbé ìjọba ìdàgbàsókè Odi-Olówó Ojúwòyè, èèyàn mẹta tí wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n ni a ti yà sọ́tọ̀ fún Ìbò yìí.
Àǹfààní míràn nìyí láti yan ènìyàn tó yẹ sípò láti ṣojú wá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ní ìlú Abuja àti Èkó pẹ̀lú ẹni tí yóò ṣojú wa ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin.
Gégé bí ẹ ṣe mọ̀, ìdàgbàsókè ló jẹwá lógún. Ìdí nìyí tí a gbọ́dọ̀ pọwọ́pọ̀ kí á ríi dájú pé a ò sọ Ìbò yìí nù rárá. A gbọ́dọ̀ mọ ẹni tó yẹ kí á dìbò wá fún.
Tí a bá ní kí á gbé yẹ̀ wò, ẹgbẹ́ ìlọsíwájú All Progressive Congress (APC) ni ẹgbẹ́ tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti gbé ètò ìṣàkóso ìlú yìí lé lọ́wọ́.
Ní agbègbè Odi-Olówó Ojúwòyè LCDA, iṣẹ́ ribiribi pọ̀ tí a lè tọ́ka sí. Ní ara iṣẹ́ náà ni ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, ìwòsàn ọ̀fẹ́, sísan owó iléèwé àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ìdánilókoowò abbl. Yàtọ̀ sí èyí, àwọn àkànṣe iṣẹ́ pọ yanturu.
Kí àwọn àǹfààní yìí máa bàa fò wá ru, tí ó bá ti di ojo ibo, yàtọ̀ sí Ìbò gboogbò ààrẹ fún Asiwaju Bola Tinubu àti Ìbò gómìnà fún Babajide Sanwo-olu, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dìbò yín fún àwọn wọ̀nyí: Adeyemi Alli, Nureni Akinsanya ati Màmá wá Dr Idiat Adebule. Àwọn ni ààrò mẹ́ta tí kìí dọbẹ̀ nù.
Adeyemi Alli yóò ṣojú Mushin 1 Federal Constituency ni Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú.
Nureni Akinsanya yóò ṣojú Mushin Constituency 1 ni ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú ní ìpínlẹ̀ Èkó.
Màmá wa Dr Idiat Adebule yóò ṣojú wá ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ìlú Abuja.
APC ni ẹ dìbò yín fún.